Yorùbá Bibeli

O. Daf 34:15-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, eti rẹ̀ si ṣi si igbe wọn.

16. Oju Oluwa kan si awọn ti nṣe buburu, lati ke iranti wọn kuro lori ilẹ.

17. Awọn olododo nke, Oluwa si gbọ́, o si yọ wọn jade ninu iṣẹ́ wọn gbogbo.

18. Oluwa mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là.

19. Ọ̀pọlọpọ ni ipọnju olododo; ṣugbọn Oluwa gbà a ninu wọn gbogbo.

20. O pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́; kò si ọkan ti o ṣẹ́ ninu wọn.

21. Ibi ni yio pa enia buburu; ati awọn ti o korira olododo yio jẹbi.

22. Oluwa rà ọkàn awọn iranṣẹ rẹ̀; ọkan ninu awọn ti o gbẹkẹle e kì yio jẹbi.