Yorùbá Bibeli

O. Daf 34:10-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Awọn ọmọ kiniun a ma ṣe alaini, ebi a si ma pa wọn: ṣugbọn awọn ti nwá Oluwa, kì yio ṣe alaini ohun ti o dara.

11. Wá, ẹnyin ọmọ, fi eti si mi: emi o kọ́ nyin li ẹ̀ru Oluwa.

12. Ọkunrin wo li o nfẹ ìye, ti o si nfẹ ọjọ pipọ, ki o le ma ri rere?

13. Pa ahọn rẹ mọ́ kuro ninu ibi, ati ète rẹ kuro li ẹ̀tan sisọ.

14. Lọ kuro ninu ibi, ki o si ma ṣe rere; ma wá alafia, ki o si lepa rẹ̀.

15. Oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, eti rẹ̀ si ṣi si igbe wọn.

16. Oju Oluwa kan si awọn ti nṣe buburu, lati ke iranti wọn kuro lori ilẹ.

17. Awọn olododo nke, Oluwa si gbọ́, o si yọ wọn jade ninu iṣẹ́ wọn gbogbo.

18. Oluwa mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là.