1. EMI o ma fi ibukún fun Oluwa nigbagbogbo: Iyìn rẹ̀ yio ma wà li ẹnu mi titi lai.
2. Ọkàn mi yio ma ṣogo rẹ̀ niti Oluwa: awọn onirẹlẹ yio gbọ́, inu wọn yio si ma dùn.
3. Gbé Oluwa ga pẹlu mi, ki a si jumọ gbé orukọ rẹ̀ leke.
4. Emi ṣe afẹri Oluwa, o si gbohùn mi; o si gbà mi kuro ninu gbogbo ìbẹru mi.
5. Nwọn wò o, imọlẹ si mọ́ wọn: oju kò si tì wọn.
6. Ọkunrin olupọnju yi kigbe pè, Oluwa si gbohùn rẹ̀, o si gbà a ninu gbogbo ipọnju rẹ̀:
7. Angeli Oluwa yi awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ ká, o si gbà wọn.