Yorùbá Bibeli

O. Daf 29:2-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ẹ fi ogo fun Oluwa, ti o yẹ fun orukọ rẹ̀; ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́.

3. Ohùn Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀: Ọlọrun ogo nsán ãrá: Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀.

4. Ohùn Oluwa li agbara; ohùn Oluwa ni ọlánla.

5. Ohùn Oluwa nfà igi kedari ya; lõtọ, Oluwa nfà igi kedari Lebanoni ya.

6. O mu wọn fò pẹlu bi ọmọ-malu; Lebanoni on Sirioni bi ọmọ agbanrere.

7. Ohùn Oluwa nyà ọwọ iná,

8. Ohùn Oluwa nmì aginju; Oluwa nmì aginju Kadeṣi.

9. Ohùn Oluwa li o nmu abo agbọnrin bi, o si fi igbo didi hàn: ati ninu tempili rẹ̀ li olukuluku nsọ̀rọ ogo rẹ̀.

10. Oluwa joko lori iṣan-omi; nitõtọ, Oluwa joko bi Ọba lailai.

11. Oluwa yio fi agbara fun awọn enia rẹ̀; Oluwa yio fi alafia busi i fun awọn enia rẹ̀.