2. Ọlọrun mi, emi gbẹkẹle ọ: máṣe jẹ ki oju ki o ti mi, máṣe jẹ ki awọn ọta mi ki o yọ̀ mi.
3. Lõtọ, maṣe jẹ ki oju ki o tì ẹnikẹni ti o duro tì ọ: awọn ti nṣẹ̀ li ainidi ni oju yio tì.
4. Fi ọ̀na rẹ hàn mi, Oluwa; kọ́ mi ni ipa tirẹ.
5. Sin mi li ọ̀na otitọ rẹ, ki o si kọ́ mi: nitori iwọ li Ọlọrun igbala mi; iwọ ni mo duro tì li ọjọ gbogbo.
6. Oluwa, ranti ãnu ati iṣeun-ifẹ rẹ ti o ni irọnu; nitoriti nwọn ti wà ni igba atijọ.
7. Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ igba-ewe mi, ati irekọja mi: gẹgẹ bi ãnu rẹ iwọ ranti mi, Oluwa, nitori ore rẹ:
8. Rere ati diduro-ṣinṣin ni Oluwa: nitorina ni yio ṣe ma kọ́ ẹlẹṣẹ li ọ̀na na.
9. Onirẹlẹ ni yio tọ́ li ọ̀na ti ó tọ́, ati onirẹlẹ ni yio kọ́ li ọ̀na rẹ̀.
10. Gbogbo ipa Oluwa li ãnu ati otitọ, fun irú awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ mọ́.