Yorùbá Bibeli

O. Daf 25:14-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Aṣiri Oluwa wà pẹlu awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, yio si fi wọn mọ̀ majẹmu rẹ̀.

15. Oju mi gbé soke si Oluwa lai; nitori ti yio fà ẹsẹ mi yọ kuro ninu àwọn na.

16. Yipada si mi, ki o si ṣãnu fun mi; nitori ti mo di ofo, mo si di olupọnju.

17. Iṣẹ́ aiya mi di pupọ: mu mi jade ninu ipọnju mi.

18. Wò ipọnju mi ati irora mi; ki o si dari gbogbo ẹ̀ṣẹ mi jì mi.

19. Wò awọn ọta mi, nwọn sá pọ̀; nwọn si korira mi ni irira ìka.

20. Pa ọkàn mi mọ́, ki o si gbà mi: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi; nitori mo gbẹkẹ̀ mi le ọ.

21. Jẹ ki ìwa-titọ ati iduro-ṣinṣin ki o pa mi mọ́: nitoriti mo duro tì ọ.

22. Rà Israeli pada, Ọlọrun, kuro ninu ìṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.