Yorùbá Bibeli

O. Daf 25:10-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Gbogbo ipa Oluwa li ãnu ati otitọ, fun irú awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ mọ́.

11. Nitori orukọ rẹ, Oluwa, dari ẹ̀ṣẹ mi jì, nitori ti o tobi.

12. Ọkunrin wo li o bẹ̀ru Oluwa? on ni yio kọ́ li ọ̀na ti yio yàn.

13. Ọkàn rẹ̀ yio joko ninu ire, irú-ọmọ rẹ̀ yio si jogun aiye.