Yorùbá Bibeli

O. Daf 22:19-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Ṣugbọn iwọ máṣe jina si mi, Oluwa: agbara mi, yara lati ràn mi lọwọ.

20. Gbà ọkàn mi lọwọ idà; ẹni mi kanna lọwọ agbara aja nì.

21. Gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì; ki iwọ ki o si gbohùn mi lati ibi iwo awọn agbanrere.

22. Emi o sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn arakunrin mi: li awujọ ijọ li emi o ma yìn ọ,

23. Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ yìn i; gbogbo ẹnyin iru-ọmọ Jakobu, ẹ yìn i logo: ki ẹ si ma bẹ̀ru rẹ̀ gidigidi, gbogbo ẹnyin irú-ọmọ Israeli.

24. Nitoriti kò kẹgan, bẹ̃ni kò korira ipọnju awọn olupọnju; bẹ̃ni kò pa oju rẹ̀ mọ́ kuro lara rẹ̀; ṣugbọn nigbati o kigbe pè e, o gbọ́.

25. Nipa tirẹ ni iyìn mi yio wà ninu ajọ nla, emi o san ẹjẹ́ mi niwaju awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀.

26. Awọn olupọnju yio jẹ, yio tẹ́ wọn lọrun: awọn ti nwá Oluwa yio yìn i: ọkàn nyin yio wà lailai:

27. Gbogbo opin aiye ni yio ranti, nwọn o si yipada si Oluwa: ati gbogbo ibatan orilẹ-ède ni yio wolẹ-sìn niwaju rẹ̀.

28. Nitori ijọba ni ti Oluwa; on si ni Bãlẹ ninu awọn orilẹ-ède.

29. Gbogbo awọn ti o sanra li aiye yio ma jẹ, nwọn o si ma wolẹ-sìn: gbogbo awọn ti nsọkalẹ lọ sinu erupẹ yio tẹriba niwaju rẹ̀, ati ẹniti kò le pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ li ãye.

30. Iru kan yio ma sìn i; a o si kà a ni iran kan fun Oluwa.

31. Nwọn o wá, nwọn o si ma sọ̀rọ ododo rẹ̀ fun awọn enia kan ti a o bí, pe, on li o ṣe eyi.