Yorùbá Bibeli

O. Daf 22:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? ti iwọ si jina si igbala mi, ati si ohùn igbe mi?

2. Ọlọrun mi, emi nkigbe li ọsan, ṣugbọn iwọ kò dahùn: ati ni igba oru emi kò dakẹ.

3. Ṣugbọn mimọ́ ni Iwọ, ẹniti o tẹ̀ iyìn Israeli do.

4. Awọn baba wa gbẹkẹle ọ: nwọn gbẹkẹle, iwọ si gbà wọn.

5. Nwọn kigbe pè ọ, a si gbà wọn: nwọn gbẹkẹle ọ, nwọn kò si dãmu.

6. Ṣugbọn kòkoro li emi, kì isi iṣe enia; ẹ̀gan awọn enia, ati ẹlẹya awọn enia.

7. Gbogbo awọn ti o ri mi nfi mi rẹrin ẹlẹya: nwọn nyọ ṣuti ète wọn, nwọn nmì ori pe,

8. Jẹ́ ki o gbẹkẹle Oluwa, on o gbà a là; jẹ ki o gbà a là nitori inu rẹ̀ dùn si i.