Yorùbá Bibeli

O. Daf 18:24-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Nitorina li Oluwa ṣe san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li oju rẹ̀.

25. Fun alãnu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alãnu; fun ẹniti o duro-ṣinṣin ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni diduro-ṣinṣin.

26. Fun ọlọkàn-mimọ́ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni ọlọkàn-mimọ́; ati fun ọlọkàn-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn li onroro.

27. Nitori iwọ o gbà awọn olupọnju; ṣugbọn iwọ o sọ oju igberaga kalẹ.

28. Nitori iwọ ni yio tàn fitila mi: Oluwa Ọlọrun mi yio tàn imọlẹ si òkunkun mi.

29. Nitori pe pẹlu rẹ emi sure là inu ogun lọ: ati pẹlu Ọlọrun mi emi fò odi kan.

30. Bi o ṣe ti Ọlọrun ni, ọ̀na rẹ̀ pé: a ti ridi ọ̀rọ Oluwa: on li apata fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e.

31. Nitori pe tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta bikoṣe Ọlọrun wa?

32. Ọlọrun li o fi agbara dì mi li amure, o si mu ọ̀na mi pé.

33. O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ àgbọnrín, o si gbé mi kà ibi giga mi.

34. O kọ́ ọwọ mi li ogun jija, tobẹ̃ ti apa mi fà ọrun idẹ.

35. Iwọ ti fi asà igbala rẹ fun mi pẹlu: ọwọ ọ̀tun rẹ si gbé mi duro, ati ìwa-pẹlẹ rẹ sọ mi di nla.

36. Iwọ sọ ìrin ẹsẹ mi di nla nisalẹ mi, ki kóko-ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀.