Yorùbá Bibeli

O. Daf 150:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Ẹ fi iyìn fun Ọlọrun ninu ibi mimọ́ rẹ̀; yìn i ninu ofurufu oju-ọrun agbara rẹ̀.

2. Yìn i nitori iṣẹ agbara rẹ̀: yìn i gẹgẹ bi titobi nla rẹ̀.

3. Fi ohùn ipè yìn i: fi ohun-èlo orin ati duru yìn i.

4. Fi ìlu ati ijó yìn i: fi ohun ọnà orin olokùn ati fère yìn i.

5. Ẹ yìn i lara aro olohùn òke: ẹ yìn i lara aro olohùn goro:

6. Jẹ ki ohun gbogbo ti o li ẹmi ki o yìn Oluwa. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.