Yorùbá Bibeli

O. Daf 147:9-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. O fi onjẹ ẹranko fun u ati fun ọmọ iwò ti ndún.

10. Kò ṣe inudidùn si agbara ẹṣin: kò ṣe inudidùn si ẹsẹ ọkunrin.

11. Oluwa nṣe inudidùn si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, si awọn ti nṣe ireti ãnu rẹ̀.

12. Yìn Oluwa, iwọ Jerusalemu; yìn Ọlọrun rẹ, iwọ Sioni.

13. Nitori ti o ti mu ọpá-idabu ẹnu-bode rẹ le; o ti busi i fun awọn ọmọ rẹ ninu rẹ.

14. O fi alafia ṣe àgbegbe rẹ, o si fi alikama didara-jù kún ọ.

15. O rán aṣẹ rẹ̀ jade wá si aiye; ọ̀rọ rẹ̀ sure tete.

16. O fi òjo-didì funni bi irun-agutan, o si fún ìri-didì ká bi ẽrú.