Yorùbá Bibeli

O. Daf 147:3-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. O mu awọn onirora aiya lara da: o di ọgbẹ wọn:

4. O ka iye awọn ìrawọ; o si sọ gbogbo wọn li orukọ.

5. Oluwa wa tobi, ati alagbara nla: oye rẹ̀ kò li opin.

6. Oluwa gbé awọn onirẹlẹ soke: o rẹ̀ awọn enia buburu si ilẹyilẹ.

7. Ẹ fi ọpẹ kọrin si Oluwa; kọrin iyìn si Ọlọrun wa lara duru: