Yorùbá Bibeli

O. Daf 147:12-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Yìn Oluwa, iwọ Jerusalemu; yìn Ọlọrun rẹ, iwọ Sioni.

13. Nitori ti o ti mu ọpá-idabu ẹnu-bode rẹ le; o ti busi i fun awọn ọmọ rẹ ninu rẹ.

14. O fi alafia ṣe àgbegbe rẹ, o si fi alikama didara-jù kún ọ.

15. O rán aṣẹ rẹ̀ jade wá si aiye; ọ̀rọ rẹ̀ sure tete.

16. O fi òjo-didì funni bi irun-agutan, o si fún ìri-didì ká bi ẽrú.

17. O dà omi didì rẹ̀ bi òkele; tali o le duro niwaju otutu rẹ̀.

18. O rán ọ̀rọ rẹ̀ jade, o si mu wọn yọ́; o mu afẹfẹ rẹ̀ fẹ, omi si nṣàn.

19. O fi ọ̀rọ rẹ̀ hàn fun Jakobu, aṣẹ rẹ̀ ati idajọ rẹ̀ fun Israeli.