Yorùbá Bibeli

O. Daf 132:13-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nitori ti Oluwa ti yàn Sioni; o ti fẹ ẹ fun ibujoko rẹ̀.

14. Eyi ni ibi isimi mi lailai: nihin li emi o ma gbe; nitori ti mo fẹ ẹ.

15. Emi o bukún onjẹ rẹ̀ pupọ̀-pupọ̀: emi o fi onjẹ tẹ́ awọn talaka rẹ̀ lọrùn.

16. Emi o si fi igbala wọ̀ awọn alufa rẹ̀: awọn enia mimọ́ rẹ̀ yio ma hó fun ayọ̀.

17. Nibẹ li emi o gbe mu iwo Dafidi yọ, emi ti ṣe ilana fitila kan fun ẹni-ororo mi.

18. Awọn ọta rẹ̀ li emi o fi itiju wọ̀: ṣugbọn lara on tikararẹ̀ li ade rẹ̀ yio ma gbilẹ.