Yorùbá Bibeli

O. Daf 121:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI o gbé oju mi si ori oke wọnnì, nibo ni iranlọwọ mi yio ti nwa?

2. Iranlọwọ mi yio ti ọwọ Oluwa wá, ti o da ọrun on aiye.

3. On kì yio jẹ́ ki ẹsẹ rẹ ki o yẹ̀; ẹniti npa ọ mọ́ kì yio tõgbe.

4. Kiyesi i, ẹniti npa Israeli mọ́, kì itõgbe, bẹ̃ni kì isùn.

5. Oluwa li olupamọ́ rẹ: Oluwa li ojiji rẹ li ọwọ ọ̀tún rẹ.

6. Orùn kì yio pa ọ nigba ọsan, tabi oṣupa nigba oru.

7. Oluwa yio pa ọ mọ́ kuro ninu ibi gbogbo: yio pa ọkàn rẹ mọ́.

8. Oluwa yio pa alọ ati àbọ rẹ mọ́ lati igba yi lọ, ati titi lailai.