Yorùbá Bibeli

O. Daf 120:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NINU ipọnju mi emi kepè Oluwa, o si da mi lohùn.

2. Oluwa, gbà ọkàn mi, lọwọ ète eke, ati lọwọ ahọn ẹ̀tan?

3. Kini ki a fi fun ọ? tabi kini ki a ṣe si ọ, ahọn ẹ̀tan.

4. Ọfà mimu alagbara, ti on ti ẹyin-iná igi juniperi!

5. Egbe ni fun mi, ti mo ṣe atipo ni Meṣeki, ti mo joko ninu agọ Kedari!

6. O ti pẹ ti ọkàn mi ti ba ẹniti o korira alafia gbe.

7. Alafia ni mo fẹ: ṣugbọn nigbati mo ba sọ̀rọ, ija ni ti wọn.