Yorùbá Bibeli

O. Daf 111:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ ma yìn Oluwa. Emi o ma yìn Oluwa tinutinu mi, ninu ijọ awọn ẹni diduro-ṣinṣin, ati ni ijọ enia.

2. Iṣẹ Oluwa tobi, iwa-kiri ni fun gbogbo awọn ti o ni ifẹ rẹ̀ ninu.

3. Iṣe rẹ̀ li ọlá on ogo, ododo rẹ̀ si duro lailai.

4. O ṣe iṣẹ iyanu rẹ̀ ni iranti: olore-ọfẹ́ li Oluwa o si kún fun ãnu.

5. O ti fi onjẹ fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀: yio ranti majẹmu rẹ̀ lailai.

6. O ti fi iṣẹ agbara rẹ̀ hàn awọn enia rẹ̀, ki o le fun wọn ni ilẹ-ini awọn keferi.

7. Otitọ ati idajọ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀; gbogbo ofin rẹ̀ li o daniloju.

8. Nwọn duro lai ati lailai, ninu otitọ ati iduro-ṣinṣin li a ṣe wọn.