Yorùbá Bibeli

O. Daf 109:17-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Bi o ti fẹ egun, bẹ̃ni ki o de si i: bi inu rẹ̀ kò ti dùn si ire, bẹ̃ni ki o jina si i.

18. Bi o ti fi egun wọ ara rẹ li aṣọ bi ẹwu rẹ̀, bẹ̃ni ki o wá si inu rẹ̀ bi omi, ati bi orõro sinu egungun rẹ̀.

19. Jẹ ki o ri fun u bi aṣọ ti o bò o lara, ati fun àmure ti o fi gbajá nigbagbogbo.

20. Eyi li ère awọn ọta mi lati ọwọ Oluwa wá, ati ti awọn ti nsọ̀rọ ibi si ọkàn mi.

21. Ṣugbọn iwọ ṣe fun mi, Ọlọrun Oluwa, nitori orukọ rẹ: nitoriti ãnu rẹ dara, iwọ gbà mi.

22. Nitoripe talaka ati olupọnju li emi aiya mi si gbọgbẹ ninu mi.

23. Emi nkọja lọ bi ojiji ti o nfà sẹhin, emi ntì soke tì sodò bi eṣú.

24. Ẽkun mi di ailera nitori igbawẹ; ẹran-ara mi si gbẹ nitori ailọra.

25. Emi di ẹ̀gan fun wọn pẹlu: nigbati nwọn wò mi, nwọn mi ori wọn.

26. Ràn mi lọwọ, Oluwa Ọlọrun mi: gbà mi gẹgẹ bi ãnu rẹ.

27. Ki nwọn ki o le mọ̀ pe ọwọ rẹ li eyi; pe Iwọ, Oluwa, li o ṣe e.

28. Nwọn o ma gegun, ṣugbọn iwọ ma sure: nigbati nwọn ba dide, ki oju ki o tì wọn; ṣugbọn iranṣẹ rẹ yio yọ̀.

29. Jẹ ki a fi ìtiju wọ̀ awọn ọta mi li aṣọ, ki nwọn ki o si fi idaru-dapọ̀ wọn bò ara, bi ẹnipe ẹ̀wu.

30. Emi o ma fi ẹnu mi yìn Oluwa gidigidi; nitõtọ, emi o ma yìn i lãrin ọ̀pọ enia.

31. Nitori ti yio duro li ọwọ ọtún olupọnju, lati gbà a lọwọ awọn ti o nda ọkàn rẹ̀ lẹbi.