Yorùbá Bibeli

O. Daf 109:14-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ki a ma ranti ẹ̀ṣẹ awọn baba rẹ̀ lọdọ Oluwa; má si jẹ ki a nù ẹ̀ṣẹ iya rẹ̀ nù.

15. Jẹ ki nwọn ki o wà niwaju Oluwa nigbagbogbo, ki o le ke iranti wọn kuro lori ilẹ.

16. Nitori ti kò ranti lati ṣãnu, ṣugbọn o ṣe inunibini si ọkunrin talaka ati olupọnju nì, ki o le pa onirobinujẹ-ọkàn.

17. Bi o ti fẹ egun, bẹ̃ni ki o de si i: bi inu rẹ̀ kò ti dùn si ire, bẹ̃ni ki o jina si i.

18. Bi o ti fi egun wọ ara rẹ li aṣọ bi ẹwu rẹ̀, bẹ̃ni ki o wá si inu rẹ̀ bi omi, ati bi orõro sinu egungun rẹ̀.

19. Jẹ ki o ri fun u bi aṣọ ti o bò o lara, ati fun àmure ti o fi gbajá nigbagbogbo.

20. Eyi li ère awọn ọta mi lati ọwọ Oluwa wá, ati ti awọn ti nsọ̀rọ ibi si ọkàn mi.

21. Ṣugbọn iwọ ṣe fun mi, Ọlọrun Oluwa, nitori orukọ rẹ: nitoriti ãnu rẹ dara, iwọ gbà mi.

22. Nitoripe talaka ati olupọnju li emi aiya mi si gbọgbẹ ninu mi.

23. Emi nkọja lọ bi ojiji ti o nfà sẹhin, emi ntì soke tì sodò bi eṣú.

24. Ẽkun mi di ailera nitori igbawẹ; ẹran-ara mi si gbẹ nitori ailọra.