Yorùbá Bibeli

O. Daf 107:7-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O si mu wọn jade nipa ọ̀na titọ, ki nwọn ki o le lọ si ilu ti nwọn o ma gbe.

8. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia!

9. Nitori ti o tẹ́ ifẹ ọkàn lọrun, o si fi ire kún ọkàn ti ebi npa.

10. Iru awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ti a dè ninu ipọnju ati ni irin;

11. Nitori ti nwọn ṣọ̀tẹ si ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn si gàn imọ Ọga-ogo:

12. Nitorina o fi lãla rẹ̀ aiya wọn silẹ: nwọn ṣubu, kò si si oluranlọwọ.

13. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn.

14. O mu wọn jade kuro ninu òkunkun ati ojiji ikú, o si fa ìde wọn ja.

15. Enia iba ma yìn Oluwa: nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia.

16. Nitori ti o fọ ilẹkun idẹ wọnni, o si ke ọpa-idabu irin wọnni li agbedemeji.

17. Aṣiwere nitori irekọja wọn, ati nitori ẹ̀ṣẹ wọn, oju npọ́n wọn.

18. Ọkàn wọn kọ̀ onjẹ-konjẹ; nwọn si sunmọ́ eti ẹnu-ọ̀na ikú.

19. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn.