Yorùbá Bibeli

O. Daf 107:30-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Nigbana ni nwọn yọ̀, nitori ti ara wọn balẹ; bẹ̃li o mu wọn wá si ebute ifẹ wọn.

31. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia!

32. Ki nwọn ki o gbé e ga pẹlu ni ijọ enia, ki nwọn ki o si yìn i ninu ijọ awọn àgba.

33. O sọ odò di aginju, ati orisun omi di ilẹ gbigbẹ;