Yorùbá Bibeli

O. Daf 107:28-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn.

29. O sọ ìji di idakẹ-rọrọ́, bẹ̃ni riru omi rẹ̀ duro jẹ.

30. Nigbana ni nwọn yọ̀, nitori ti ara wọn balẹ; bẹ̃li o mu wọn wá si ebute ifẹ wọn.

31. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia!

32. Ki nwọn ki o gbé e ga pẹlu ni ijọ enia, ki nwọn ki o si yìn i ninu ijọ awọn àgba.

33. O sọ odò di aginju, ati orisun omi di ilẹ gbigbẹ;

34. Ilẹ eleso di aṣálẹ̀, nitori ìwa-buburu awọn ti o wà ninu rẹ̀.

35. O sọ aginju di adagun omi, ati ilẹ gbigbẹ di orisun omi.

36. Nibẹ li o si mu awọn ti ebi npa joko, ki nwọn ki o le tẹ ilu do, lati ma gbe.

37. Lati fún irugbin si oko, ki nwọn si gbìn àgbala ajara, ti yio ma so eso ọ̀pọlọpọ.