27. Nwọn nta gbọ̀ngbọ́n sihin sọhun, nwọn nta gbọ̀ngbọ́n bi ọmuti enia, ọgbọ́n wọn si de opin.
28. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn.
29. O sọ ìji di idakẹ-rọrọ́, bẹ̃ni riru omi rẹ̀ duro jẹ.
30. Nigbana ni nwọn yọ̀, nitori ti ara wọn balẹ; bẹ̃li o mu wọn wá si ebute ifẹ wọn.
31. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia!
32. Ki nwọn ki o gbé e ga pẹlu ni ijọ enia, ki nwọn ki o si yìn i ninu ijọ awọn àgba.
33. O sọ odò di aginju, ati orisun omi di ilẹ gbigbẹ;
34. Ilẹ eleso di aṣálẹ̀, nitori ìwa-buburu awọn ti o wà ninu rẹ̀.
35. O sọ aginju di adagun omi, ati ilẹ gbigbẹ di orisun omi.
36. Nibẹ li o si mu awọn ti ebi npa joko, ki nwọn ki o le tẹ ilu do, lati ma gbe.
37. Lati fún irugbin si oko, ki nwọn si gbìn àgbala ajara, ti yio ma so eso ọ̀pọlọpọ.