Yorùbá Bibeli

O. Daf 107:18-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ọkàn wọn kọ̀ onjẹ-konjẹ; nwọn si sunmọ́ eti ẹnu-ọ̀na ikú.

19. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn.

20. O rán ọ̀rọ rẹ̀, o si mu wọn lara da, o si gbà wọn kuro ninu iparun wọn.

21. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia.

22. Si jẹ ki nwọn ki o ru ẹbọ ọpẹ, ki nwọn ki o si fi orin ayọ̀ sọ̀rọ iṣẹ rẹ̀.

23. Awọn ti nsọkalẹ lọ si okun ninu ọkọ̀, ti nwọn nṣiṣẹ ninu omi nla.

24. Awọn wọnyi ri iṣẹ Oluwa, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ninu ibú.

25. Nitori ti o paṣẹ, o si mu ìji fẹ, ti o gbé riru rẹ̀ soke.

26. Nwọn gòke lọ si ọrun, nwọn si tún sọkalẹ lọ si ibú; ọkàn wọn di omi nitori ipọnju.

27. Nwọn nta gbọ̀ngbọ́n sihin sọhun, nwọn nta gbọ̀ngbọ́n bi ọmuti enia, ọgbọ́n wọn si de opin.

28. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn.