Yorùbá Bibeli

O. Daf 107:15-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Enia iba ma yìn Oluwa: nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia.

16. Nitori ti o fọ ilẹkun idẹ wọnni, o si ke ọpa-idabu irin wọnni li agbedemeji.

17. Aṣiwere nitori irekọja wọn, ati nitori ẹ̀ṣẹ wọn, oju npọ́n wọn.

18. Ọkàn wọn kọ̀ onjẹ-konjẹ; nwọn si sunmọ́ eti ẹnu-ọ̀na ikú.

19. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn.

20. O rán ọ̀rọ rẹ̀, o si mu wọn lara da, o si gbà wọn kuro ninu iparun wọn.

21. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia.

22. Si jẹ ki nwọn ki o ru ẹbọ ọpẹ, ki nwọn ki o si fi orin ayọ̀ sọ̀rọ iṣẹ rẹ̀.

23. Awọn ti nsọkalẹ lọ si okun ninu ọkọ̀, ti nwọn nṣiṣẹ ninu omi nla.

24. Awọn wọnyi ri iṣẹ Oluwa, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ninu ibú.

25. Nitori ti o paṣẹ, o si mu ìji fẹ, ti o gbé riru rẹ̀ soke.