Yorùbá Bibeli

O. Daf 107:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

2. Jẹ ki awọn ẹni-irapada Oluwa ki o wi bẹ̃, ẹniti o rà pada kuro ni ọwọ ọta nì.

3. O si kó wọn jọ lati ilẹ wọnnì wá, lati ila-õrun wá, ati lati ìwọ-õrun, lati ariwa, ati lati okun wá.