Yorùbá Bibeli

O. Daf 107:1-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

2. Jẹ ki awọn ẹni-irapada Oluwa ki o wi bẹ̃, ẹniti o rà pada kuro ni ọwọ ọta nì.

3. O si kó wọn jọ lati ilẹ wọnnì wá, lati ila-õrun wá, ati lati ìwọ-õrun, lati ariwa, ati lati okun wá.

4. Nwọn nrìn ka kiri li aginju ni ibi ti ọ̀na kò si: nwọn kò ri ilu lati ma gbe.

5. Ebi pa wọn, ongbẹ si gbẹ wọn, o rẹ̀ ọkàn wọn ninu wọn.

6. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn,

7. O si mu wọn jade nipa ọ̀na titọ, ki nwọn ki o le lọ si ilu ti nwọn o ma gbe.

8. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia!

9. Nitori ti o tẹ́ ifẹ ọkàn lọrun, o si fi ire kún ọkàn ti ebi npa.

10. Iru awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ti a dè ninu ipọnju ati ni irin;

11. Nitori ti nwọn ṣọ̀tẹ si ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn si gàn imọ Ọga-ogo:

12. Nitorina o fi lãla rẹ̀ aiya wọn silẹ: nwọn ṣubu, kò si si oluranlọwọ.

13. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn.

14. O mu wọn jade kuro ninu òkunkun ati ojiji ikú, o si fa ìde wọn ja.

15. Enia iba ma yìn Oluwa: nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia.

16. Nitori ti o fọ ilẹkun idẹ wọnni, o si ke ọpa-idabu irin wọnni li agbedemeji.

17. Aṣiwere nitori irekọja wọn, ati nitori ẹ̀ṣẹ wọn, oju npọ́n wọn.

18. Ọkàn wọn kọ̀ onjẹ-konjẹ; nwọn si sunmọ́ eti ẹnu-ọ̀na ikú.