Yorùbá Bibeli

Neh 1:4-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. O si ṣe nigbati mo gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, mo joko, mo si sọkun, mo si ṣọ̀fọ ni iye ọjọ, mo si gbãwẹ, mo si gbàdura niwaju Ọlọrun ọrun.

5. Mo si wipe, Emi mbẹ̀bẹ lọdọ rẹ, Oluwa Ọlọrun ọrun, ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ti npa majẹmu ati ãnu mọ fun awọn ti o fẹ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ:

6. Tẹ́ eti rẹ silẹ̀ nisisiyi, ki o si ṣi oju rẹ, ki iwọ ba le gbọ́ adura iranṣẹ rẹ, ti mo ngbà niwaju rẹ nisisiyi, tọsan toru fun awọn ọmọ Israeli iranṣẹ rẹ, ti mo si jẹwọ ẹ̀ṣẹ awọn ọmọ Israeli ti a ti ṣẹ̀ si ọ: ati emi ati ile baba mi ti ṣẹ̀.

7. Awa ti huwa ibàjẹ si ọ, awa kò si pa ofin ati ilana ati idajọ mọ, ti iwọ pa li aṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ.

8. Emi bẹ̀ ọ, ranti ọ̀rọ ti iwọ pa laṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ, wipe, Bi ẹnyin ba ṣẹ̀, emi o tú nyin kakiri sãrin awọn orilẹ-ède: