Nah

  1. 1
  2. 2
  3. 3

Yorùbá Bibeli

Nah 1 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ-ÌMỌ̀ niti Ninefe. Iwe iran Nahumu ara Elkoṣi.

Ibinu OLUWA sí Ìlú Ninefe

2. Ọlọrun njowu, Oluwa si ngbẹsan; Oluwa ngbẹsan, o si kún fun ibinu; Oluwa ngbẹsan li ara awọn ọta rẹ̀, o si fi ibinu de awọn ọta rẹ̀.

3. Oluwa lọra lati binu, o si tobi li agbara, ni didasilẹ̀ kì yio da enia buburu silẹ: Oluwa ni ọ̀na rẹ̀ ninu ãjà ati ninu ìji, awọsanma si ni ekuru ẹsẹ̀ rẹ̀.

4. O ba okun wi, o si mu ki o gbẹ, o si sọ gbogbo odò di gbigbẹ: Baṣani di alailera, ati Karmeli, itànna Lebanoni si rọ.

5. Awọn oke-nla mì nitori rẹ̀, ati awọn oke kékèké di yiyọ́, ilẹ aiye si joná niwaju rẹ̀, ani aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀.

6. Tani o le duro niwaju ibinu rẹ̀? tani o si le duro gba gbigboná ibinu rẹ̀? a dà ibinu rẹ̀ jade bi iná, on li o si fọ́ awọn apata.

7. Rere li Oluwa, ãbo li ọjọ ipọnju; on si mọ̀ awọn ti o gbẹkẹ̀le e.

8. Ṣugbọn ikún omi akunrekọja li on fi ṣe iparun ibẹ̀ na de opin, okùnkun yio si ma lepa awọn ọta rẹ̀.

9. Kili ẹnyin ngbirò si Oluwa? on o ṣe iparun de opin, ipọnju kì yio dide lẹrinkeji.

10. Nitori sã ti a ba ká wọn jọ bi ẹ̀gun, ati sã ti wọn iba mu amupara bi ọmùti, a o run wọn gẹgẹ bi koriko ti o ti gbẹ de opin.

11. Ẹnikan ti ọdọ rẹ jade wá, ti o ngbirò ibi si Oluwa, olugbìmọ buburu.

12. Bayi ni Oluwa wi; bi nwọn tilẹ pé, ti nwọn si pọ̀ niye, ṣugbọn bayi ni a o ke nwọn lulẹ, nigbati on o ba kọja. Bi mo tilẹ ti pọn ọ loju, emi kì yio pọn ọ loju mọ.

13. Nitori nisisiyi li emi o fà ajàga rẹ̀ kuro li ọrun rẹ, emi o si dá idè rẹ wọnni li agbede-meji.

14. Oluwa si ti fi aṣẹ kan lelẹ nitori rẹ pe, ki a má ṣe gbìn ninu orukọ rẹ mọ: lati inu ile ọlọrun rẹ wá li emi o ke ere fifin ati ere didà kuro: emi o wà ibojì rẹ; nitori ẹgbin ni iwọ.

15. Wò o lori oke nla ẹsẹ̀ ẹniti o mu ihìn rere wá, ẹniti o nkede alafia! Iwọ Juda, pa aṣẹ rẹ ti o ni irònu mọ, san ẹ̀jẹ́ rẹ: nitori enia buburu kì yio kọja lãrin rẹ mọ; a ti ké e kuro patapata.