Yorùbá Bibeli

Mik 5:6-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nwọn o si fi idà pa ilẹ Assiria run, ati ilẹ Nimrodu ni àbawọ̀ inu rẹ̀: yio si gbà wa lọwọ ara Assiria nigbati o ba wá ilẹ wa, ati nigbati o ba si ntẹ̀ àgbegbe wa mọlẹ.

7. Iyokù Jakobu yio si wà lãrin ọ̀pọ enia bi irì lati ọdọ Oluwa wá, bi ọwarà òjo lori koriko, ti kì idara duro de enia, ti kì isi duro de awọn ọmọ enia.

8. Iyokù Jakobu yio si wà lãrin awọn Keferi, lãrin ọ̀pọ enia bi kiniun, lãrin awọn ẹranko igbo, bi ọmọkiniun lãrin agbo agutan; eyiti, bi o ba là a ja, ti itẹ̀ mọlẹ, ti isi ifa ya pẹrẹpẹrẹ, kò si ẹniti yio gbalà.

9. A o gbe ọwọ́ rẹ soke sori awọn ọ̀ta rẹ, gbogbo awọn ọ̀ta rẹ, li a o si ke kuro.

10. Yio si ṣe li ọjọ na, ni Oluwa wi, ti emi o ke awọn ẹṣin rẹ kuro lãrin rẹ, emi o si pa awọn kẹkẹ́ ogun rẹ run.

11. Emi o si ke ilu-nla ilẹ rẹ kuro, emi o si tì gbogbo odi rẹ ṣubu: