Yorùbá Bibeli

Mik 3:8-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ṣugbọn nitõtọ emi kún fun agbara nipa ẹmi Oluwa, ati fun idajọ, ati fun ipá, lati sọ irekọja Jakobu fun u, ati lati sọ ẹ̀ṣẹ Israeli fun u.

9. Gbọ́ eyi, emi bẹ̀ nyin, ẹnyin olori ile Jakobu; ati awọn alakoso ile Israeli, ti o korira idajọ, ti o si yi otitọ pada.

10. Ti o fi ẹjẹ kọ́ Sioni, ati Jerusalemu pẹlu iwà ẹ̀ṣẹ.

11. Awọn olori rẹ̀ nṣe idajọ nitori ère, awọn alufa rẹ̀ nkọ́ni fun ọyà, awọn woli rẹ̀ si nsọtẹlẹ fun owo: sibẹ ni nwọn o gbẹkẹle Oluwa, wipe, Oluwa kò ha wà lãrin wa? ibi kan kì yio ba wa.

12. Nitorina nitori nyin ni a o ṣe ro Sioni bi oko, Jerusalemu yio si di okìti, ati oke-nla ile bi ibi giga igbo.