Yorùbá Bibeli

Mik 3:3-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Awọn ẹniti o si jẹ ẹran-ara awọn enia mi pẹlu, ti nwọn si họ́ awọ-ara wọn kuro lara wọn, nwọn si fọ́ egungun wọn, nwọn si ke wọn wẹwẹ, bi ti ikòko, ati gẹgẹ bi ẹran ninu òdu.

4. Nigbana ni nwọn o kigbe pe Oluwa, ṣugbọn on kì yio gbọ́ ti wọn: on o tilẹ pa oju rẹ̀ mọ kuro lọdọ wọn li akoko na, gẹgẹ bi nwọn ti huwà alaifi ri ninu gbogbo iṣe wọn.

5. Bayi ni Oluwa wi niti awọn woli ti nṣì awọn enia mi li ọ̀na, ti nfi ehín wọn bù ni ṣán, ti o si nkigbe wipe, Alafia; on ẹniti kò fi nkan si wọn li ẹnu, awọn na si mura ogun si i.

6. Nitorina oru yio ru nyin, ti ẹnyin kì yio fi ri iran; òkunkun yio si kùn fun nyin, ti ẹnyin kì o fi le sọtẹlẹ; õrùn yio si wọ̀ lori awọn woli, ọjọ yio si ṣokùnkun lori wọn.

7. Oju yio si tì awọn ariran, awọn alasọtẹlẹ̀ na yio si dãmu: nitõtọ, gbogbo wọn o bò ete wọn: nitori idahùn kò si lati ọdọ Ọlọrun.

8. Ṣugbọn nitõtọ emi kún fun agbara nipa ẹmi Oluwa, ati fun idajọ, ati fun ipá, lati sọ irekọja Jakobu fun u, ati lati sọ ẹ̀ṣẹ Israeli fun u.

9. Gbọ́ eyi, emi bẹ̀ nyin, ẹnyin olori ile Jakobu; ati awọn alakoso ile Israeli, ti o korira idajọ, ti o si yi otitọ pada.

10. Ti o fi ẹjẹ kọ́ Sioni, ati Jerusalemu pẹlu iwà ẹ̀ṣẹ.