Yorùbá Bibeli

Mat 9:13-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ṣugbọn ẹ lọ ẹ si kọ́ bi ã ti mọ̀ eyi si, Anu li emi nfẹ, kì iṣe ẹbọ: nitori emi kò wá lati pè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.

14. Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Johanu tọ̀ ọ wá wipe, Èṣe ti awa ati awọn Farisi fi ngbàwẹ nigbagbogbo, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko gbàwẹ?

15. Jesu si wi fun wọn pe, Awọn ọmọ ile iyawo ha le gbàwẹ, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn ó gbãwẹ.

16. Ko si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun lẹ ogbologbó ẹ̀wu; nitori eyi ti a fi lẹ ẹ o mu kuro li oju ẹ̀lẹ, aṣọ na a si mã ya siwaju.

17. Bẹ̃ni ko si ẹniti ifi waini titun sinu ogbologbo igo-awọ; bi a ba ṣe bẹ̃, igo-awọ yio bẹ́, waini a si tú jade, igo-awọ a si ṣegbe; ṣugbọn waini titun ni nwọn ifi sinu igo-awọ titun, awọn mejeji a si ṣe dede.

18. Bi o ti nsọ nkan wọnyi fun wọn, kiyesi i, ijoye kan tọ̀ ọ wá, o si tẹriba fun u, wipe, Ọmọbinrin mi kú nisisiyi, ṣugbọn wá fi ọwọ́ rẹ le e, on ó si yè.

19. Jesu dide, o si ba a lọ, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

20. Si kiyesi i, obinrin kan ti o ni isun ẹ̀jẹ li ọdún mejila, o wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀.

21. Nitori o wi ninu ara rẹ̀ pe, Bi mo ba sá le fi ọwọ́ kàn aṣọ rẹ̀, ara mi ó da.

22. Nigbati Jesu si yi ara rẹ̀ pada ti o ri i, o wipe, Ọmọbinrin, tújuka, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada. A si mu obinrin na larada ni wakati kanna.

23. Nigbati Jesu si de ile ijoye na, o ba awọn afunfere ati ọ̀pọ enia npariwo.

24. O wi fun wọn pe, Bìla; nitori ọmọbinrin na ko kú, sisùn li o sùn. Nwọn si fi rín ẹrin ẹlẹyà.

25. Ṣugbọn nigbati a si ṣe ti awọn enia jade, o bọ sile, o si fà ọmọbinrin na li ọwọ́ soke; bẹ̃li ọmọbinrin na si dide.

26. Okikí si kàn ká gbogbo ilẹ nã.