Yorùbá Bibeli

Mat 9:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si bọ sinu ọkọ̀, o rekọja, o si wá si ilu on tikararẹ̀.

2. Si kiyesi i, nwọn gbé ọkunrin kan ti o li ẹ̀gba wá sọdọ rẹ̀, o dubulẹ lori akete; nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọkunrin, tújuka, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.

3. Si kiyesi i, awọn ọkan ninu awọn akọwe nwi ninu ara wọn pe, ọkunrin yi nsọrọ-odi.

4. Jesu si mọ̀ ìro inu wọn, o wipe, Nitori kili ẹnyin ṣe nrò buburu ninu nyin?

5. Ewo li o rọrun ju, lati wipe, A dari ẹṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, ki o si mã rìn?

6. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, Ọmọ enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o si wi fun alarun ẹ̀gba na pe,) Dide, si gbé akete rẹ, ki o si mã lọ ile rẹ.

7. O si dide, o si lọ ile rẹ̀.