Yorùbá Bibeli

Mat 7:5-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Iwọ agabagebe, tètekọ́ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ kuro.

6. Ẹ máṣe fi ohun mimọ́ fun ajá, ki ẹ má si ṣe sọ ọṣọ́ nyin siwaju ẹlẹdẹ, ki nwọn má ba fi ẹsẹ tẹ̀ wọn mọlẹ, nwọn a si yipada ẹ̀wẹ, nwọn a si bù nyin ṣán.

7. Bère, a o si fifun nyin; wá kiri, ẹnyin o si ri; kànkun, a o si ṣí i silẹ fun nyin.

8. Nitori ẹnikẹni ti o bère nri gbà; ẹniti o ba si wá kiri nri: ẹniti o ba si nkànkun, li a o ṣí i silẹ fun.

9. Tabi ọkunrin wo ni ti mbẹ ninu nyin, bi ọmọ rẹ̀ bère akara, ti o jẹ fi okuta fun u?

10. Tabi bi o bère ẹja, ti o jẹ fun u li ejò?

11. Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu, ba mọ̀ bi ã ti fi ẹ̀bun rere fun awọn ọmọ nyin, melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ohun rere fun awọn ti o bère lọwọ rẹ̀?

12. Nitorina gbogbo ohunkohun ti ẹnyin ba nfẹ ki enia ki o ṣe si nyin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe si wọn gẹgẹ; nitori eyi li ofin ati awọn woli.

13. Ẹ ba ẹnu-ọ̀na hihá wọle; gbòro li ẹnu-ọ̀na na, ati onibú li oju ọ̀na na ti o lọ si ibi iparun; òpọlọpọ li awọn ẹniti mba ibẹ̀ wọle.

14. Nitori pe hihá ni ẹnu-ọ̀na na, ati toro li oju-ọ̀na na, ti o lọ si ibi ìye, diẹ li awọn ẹniti o nrin i.

15. Ẹ mã kiyesi awọn eke woli ti o ntọ̀ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu.

16. Eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn. Enia a mã ká eso ajara lori ẹgún ọgàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹ̀wọn?

17. Gẹgẹ bẹ̃ gbogbo igi rere ni iso eso rere; ṣugbọn igi buburu ni iso eso buburu.

18. Igi rere ko le so eso buburu, bẹ̃ni igi buburu ko si le so eso rere.

19. Gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a ké e lùlẹ, a si wọ́ ọ sọ sinu iná.

20. Nitorina nipa eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn.