Yorùbá Bibeli

Mat 7:15-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ẹ mã kiyesi awọn eke woli ti o ntọ̀ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu.

16. Eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn. Enia a mã ká eso ajara lori ẹgún ọgàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹ̀wọn?

17. Gẹgẹ bẹ̃ gbogbo igi rere ni iso eso rere; ṣugbọn igi buburu ni iso eso buburu.

18. Igi rere ko le so eso buburu, bẹ̃ni igi buburu ko si le so eso rere.

19. Gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a ké e lùlẹ, a si wọ́ ọ sọ sinu iná.

20. Nitorina nipa eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn.

21. Ki iṣe gbogbo ẹniti npè mi li Oluwa, Oluwa, ni yio wọ ijọba ọrun; bikoṣe ẹniti nṣe ifẹ ti Baba mi ti mbẹ li ọrun.

22. Ọpọlọpọ enia ni yio wi fun mi li ọjọ na pe, Oluwa, Oluwa, awa ko ha sọtẹlẹ li orukọ rẹ? ati orukọ rẹ ki a fi lé awọn ẹmi èṣu jade? ati li orukọ rẹ ki a fi ṣe ọ̀pọ iṣẹ iyanu nla?