Yorùbá Bibeli

Mat 27:43-58 Yorùbá Bibeli (YCE)

43. O gbẹkẹle Ọlọrun; jẹ ki o gbà a là nisisiyi, bi o ba fẹran rẹ̀: o sá wipe, Ọmọ Ọlọrun li emi.

44. Awọn olè ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nfi eyi na gún u loju bakanna.

45. Lati wakati kẹfa, ni òkunkun ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan.

46. Niwọn wakati kẹsan ni Jesu si kigbe li ohùn rara wipe, Eli, Eli, lama sabaktani? eyini ni, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ?

47. Nigbati awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọkunrin yi npè Elijah.

48. Lojukanna ọkan ninu wọn si sare, o mu kànìnkànìn, o tẹ̀ ẹ bọ̀ inu ọti kikan, o fi le ori ọpá iyè, o si fifun u mu.

49. Awọn iyokù wipe, Ẹ fi silẹ̀, ẹ jẹ ki a mã wò bi Elijah yio wá gbà a là.

50. Jesu si tún kigbe li ohùn rara, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ.

51. Si wo o, aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ; ilẹ si mì titi, awọn apata si sán;

52. Awọn isà okú si ṣí silẹ; ọ̀pọ okú awọn ẹni mimọ́ ti o ti sùn si jinde,

53. Nwọn ti inu isà okú wọn jade lẹhin ajinde rẹ̀, nwọn si wá si ilu mimọ́, nwọn si farahàn ọ̀pọlọpọ enia.

54. Nigbati balogun ọrún, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, ti nwọn nṣọ́ Jesu, ri isẹlẹ na, ati ohun wọnni ti ó ṣẹ̀, èru ba wọn gidigidi, nwọn wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li eyi iṣe.

55. Awọn obinrin pipọ, li o wà nibẹ̀, ti nwọn ńwòran lati òkẽrè, awọn ti o ba Jesu ti Galili wá, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u:

56. Ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu ati Jose, ati iya awọn ọmọ Sebede.

57. Nigbati alẹ si lẹ, ọkunrin ọlọrọ̀ kan ti Arimatea wá, ti a npè ni Josefu, ẹniti on tikararẹ̀ iṣe ọmọ-ẹhin Jesu pẹlu:

58. O tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu. Nigbana ni Pilatu paṣẹ ki a fi okú na fun u.