Yorùbá Bibeli

Mat 24:40-51 Yorùbá Bibeli (YCE)

40. Nigbana li ẹni meji yio wà li oko; a o mu ọkan, a o si fi èkejì silẹ.

41. Awọn obinrin meji yio jùmọ ma lọ̀ ọlọ pọ̀; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ.

42. Nitorina ẹ mã ṣọna: nitori ẹnyin kò mọ̀ wakati ti Oluwa nyin yio de.

43. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o mọ̀ eyi pe, bãle ile iba mọ̀ wakati na ti olè yio wá, iba ma ṣọna, on kì ba ti jẹ́ ki a runlẹ ile rẹ̀.

44. Nitorina ki ẹnyin ki o mura silẹ: nitori ni wakati ti ẹnyin kò rò tẹlẹ li Ọmọ-enia yio de.

45. Tani iṣe olõtọ ati ọlọgbọn ọmọ-ọdọ, ẹniti oluwa rẹ̀ fi ṣe olori ile rẹ̀, lati fi onjẹ wọn fun wọn li akokò?

46. Alabukún-fun li ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ẹniti yio bá a ki o mã ṣe bẹ̃.

47. Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, On o fi ṣe olori gbogbo ohun ti o ni.

48. Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ buburu na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi fà àbọ rẹ̀ sẹhin;

49. Ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn ọmọ-ọdọ ẹlẹgbẹ rẹ̀, ati si ijẹ ati si imu pẹlu awọn ọ̀muti;

50. Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti, ati ni wakati ti kò daba.

51. Yio si jẹ ẹ ni ìya gidigidi, yio yàn ipa rẹ̀ pẹlu awọn agabagebe, nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.