Yorùbá Bibeli

Mat 21:14-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ati awọn afọju ati awọn amukun wá sọdọ rẹ̀ ni tẹmpili; o si mu wọn larada.

15. Ṣugbọn nigbati awọn olori alufa ati awọn akọwe ri ohun iyanu ti o ṣe, ati bi awọn ọmọ kekeke ti nke ni tẹmpili, wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi; inu bi wọn gidigidi,

16. Nwọn si wi fun u pe, Iwọ gbọ́ eyiti awọn wọnyi nwi? Jesu si wi fun wọn pe, Bẹ̃ni; ẹnyin kò ti kà a ninu iwe pe, Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ́ ati awọn ọmọ-ọmu ni iwọ ti mu iyìn pé?

17. O si fi wọn silẹ, o jade kuro ni ilu na lọ si Betani; o wọ̀ sibẹ̀.

18. Nigbati o di owurọ̀, bi o ti npada bọ̀ si Jerusalemu, ebi npa a.

19. Nigbati o ri igi ọ̀pọtọ li ọ̀na, o lọ sibẹ̀, kò si ri ohun kan lori rẹ̀, bikoṣe kìki ewé, o si wi fun u pe, Ki eso ki o má so lori rẹ lati oni lọ titi lailai. Lojukanna igi ọpọtọ na gbẹ.

20. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, ẹnu yà wọn, nwọn wipe, Igi ọpọtọ yi mà tete gbẹ?

21. Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́, ti ẹ kò ba si ṣiyemeji, ẹnyin kì yio ṣe kìki eyi ti a ṣe si igi ọpọtọ yi, ṣugbọn bi ẹnyin ba tilẹ wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ́ sinu okun, yio ṣẹ.

22. Ohunkohun gbogbo ti ẹnyin ba bère ninu adura pẹlu igbagbọ́, ẹnyin o ri gbà.

23. Nigbati o si de inu tẹmpili, awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá sọdọ rẹ̀ bi o ti nkọ́ awọn enia; nwọn wipe, Aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi?

24. Jesu si dahun o si wi fun wọn pe, Emi ó si bi nyin lẽre ohun kan pẹlu, bi ẹnyin ba sọ fun mi, emi o si sọ fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi:

25. Baptismu Johanu, nibo li o ti wá? lati ọrun wá ni, tabi lati ọdọ enia? Nwọn si ba ara wọn gbèro, wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni, on o wi fun wa pe, Ẽha ti ṣe ti ẹnyin ko fi gbà a gbọ́?

26. Ṣugbọn bi awa ba si wipe, Lati ọdọ enia; awa mbẹ̀ru ijọ enia, nitori gbogbo wọn kà Johanu si wolĩ.