Yorùbá Bibeli

Mat 15:9-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ṣugbọn lasan ni nwọn ntẹriba fun mi, nwọn nfi ofin enia kọ́ni fun ẹkọ.

10. O si pè ijọ enia, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ ki o si ye nyin;

11. Ki iṣe ohun ti o wọni li ẹnu lọ, ni isọ enia di alaimọ́; bikoṣe eyi ti o ti ẹnu jade wá, eyini ni isọ enia di alaimọ́.

12. Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ pe, awọn Farisi binu lẹhin igbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ yi?

13. O si dahùn, o wi fun wọn pe, Igikigi ti Baba mi ti mbẹ li ọrun kò ba gbìn, a o fà a tu kuro.

14. Ẹ jọwọ wọn si: afọju ti nfọ̀nahàn afọju ni nwọn. Bi afọju ba si nfọnahàn afọju, awọn mejeji ni yio ṣubu sinu ihò.

15. Nigbana ni Peteru dahùn o si wi fun u pe, Sọ itumọ owe yi fun wa.

16. Jesu si wipe, Ẹnyin pẹlu wà li aimoye sibẹ?

17. Ẹnyin ko mọ̀ pe, ohunkohun ti o ba bọ si ẹnu lọ si inu, a si yà a jade?

18. Ṣugbọn nkan wọnni ti o ti ẹnu jade, inu ọkàn li o ti wá; nwọn a si sọ enia di alaimọ́.

19. Nitori lati inu ọkàn ni iro buburu ti ijade wá, ipania, panṣaga, àgbere, olè, ẹ̀rí èké ati ọ̀rọ buburu;