Yorùbá Bibeli

Mat 15:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA li awọn akọwe ati awọn Farisi ti Jerusalemu tọ̀ Jesu wá, wipe,

2. Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ fi nrú ofin atọwọdọwọ awọn alàgba? nitoriti nwọn kì iwẹ̀ ọwọ́ wọn nigbati nwọn ba njẹun.

3. Ṣugbọn o dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin pẹlu nfi ofin atọwọdọwọ nyin rú ofin Ọlọrun?

4. Nitori Ọlọrun ṣòfin, wipe, Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ: ati ẹniti o ba sọrọ baba ati iya rẹ̀ ni buburu, ẹ jẹ ki o kú ikú rẹ̀.

5. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ẹnikẹni ti o ba wi fun baba tabi iya rẹ̀ pe, Ẹbùn li ohunkohun ti iwọ iba fi jère lara mi,

6. Ti ko si bọ̀wọ fun baba tabi iya rẹ̀, o bọ́. Bẹ̃li ẹnyin sọ ofin Ọlọrun di asan nipa ofin atọwọdọwọ nyin.

7. Ẹnyin agabagebe, otitọ ni Isaiah sọtẹlẹ nipa ti nyin, wipe,

8. Awọn enia yi nfi ẹnu wọn sunmọ mi, nwọn si nfi ète wọn bọla fun mi; ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi.

9. Ṣugbọn lasan ni nwọn ntẹriba fun mi, nwọn nfi ofin enia kọ́ni fun ẹkọ.

10. O si pè ijọ enia, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ ki o si ye nyin;

11. Ki iṣe ohun ti o wọni li ẹnu lọ, ni isọ enia di alaimọ́; bikoṣe eyi ti o ti ẹnu jade wá, eyini ni isọ enia di alaimọ́.

12. Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ pe, awọn Farisi binu lẹhin igbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ yi?