Yorùbá Bibeli

Mat 14:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI akokò na ni Herodu tetrarki gbọ́ okikí Jesu,

2. O si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li eyi; o jinde kuro ninu okú; nitorina ni iṣẹ agbara ṣe hàn lara rẹ̀.

3. Herodu sá ti mu Johanu, o dè e, o si fi i sinu tubu, nitori Herodia aya Filippi arakunrin rẹ̀.

4. Johanu sá ti wi fun u pe, ko tọ́ fun ọ lati ni i.

5. Nigbati o si nfẹ pa a, o bẹ̀ru ijọ enia, nitoriti nwọn kà a si wolĩ.

6. Ṣugbọn nigbati a nṣe iranti ọjọ ibí Herodu, ọmọbinrin Herodia jó lãrin wọn, inu Herodu si dùn.

7. Nitorina li o ṣe fi ibura ṣe ileri lati fun u li ohunkohun ti o ba bère.

8. Ẹniti iya rẹ̀ ti kọ́ tẹlẹ ri, o wipe, Fun mi li ori Johanu Baptisti nihinyi ninu awopọkọ.

9. Inu ọba si bajẹ: ṣugbọn nitori ibura rẹ̀, ati awọn ti o bá a joko tì onjẹ, o ni ki a fi fun u.

10. O si ranṣẹ lọ, o bẹ́ Johanu li ori ninu tubu.

11. A si gbé ori rẹ̀ wá ninu awopọkọ, a si fifun ọmọbinrin na; o si gbé e tọ̀ iya rẹ̀ lọ.

12. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wá, nwọn gbé okú rẹ̀ sin, nwọn si lọ, nwọn si wi fun Jesu.

13. Nigbati Jesu si gbọ́, o dide kuro nibẹ̀, o ba ti ọkọ̀ lọ si ibi ijù, on nikan; nigbati awọn enia si gbọ́, nwọn si ti ilu wọn rìn tọ̀ ọ li ẹsẹ.

14. Jesu jade lọ, o ri ọ̀pọlọpọ enia, inu rẹ̀ si yọ́ si wọn, o si ṣe dida arùn ara wọn.