Yorùbá Bibeli

Mat 10:19-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Nigbati nwọn ba si fi nyin le wọn lọwọ, ẹ máṣe ṣàniyan pe, bawo tabi kili ẹnyin o wi? nitoriti a o fi ohun ti ẹnyin o wi fun nyin ni wakati kanna.

20. Nitoripe ki iṣe ẹnyin li o nsọ, ṣugbọn Ẹmí Baba nyin ni nsọ ninu nyin.

21. Arakunrin yio si fi arakunrin rẹ̀ fun pipa, ati baba yio si fi ọmọ rẹ̀ fun pipa: awọn ọmọ yio si dide si awọn obi wọn nwọn o si mu ki a pa wọn.

22. Gbogbo enia yio si korira nyin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà.

23. Ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣe inunibini si nyin ni ilu yi, ẹ sá lọ si omiran: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ẹnyin kì ó le rekọja gbogbo ilu Israeli tan titi Ọmọ enia ó fi de.

24. Ọmọ-ẹhin kì ijù olukọ rẹ̀ lọ, bẹ̃ni ọmọ-ọdọ ẹni ki ijù oluwa rẹ̀ lọ.

25. O to fun ọmọ-ẹhin ki o dabi olukọ rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ ki o dabi oluwa rẹ̀. Bi nwọn ba pè bãle ile ni Beelsebubu, melomelo ni awọn ara ile rẹ̀?

26. Nitorina ẹ má fòiya wọn; nitoriti ko si ohun ti a bò, ti ki o farahàn; ati eyi ti o farasin, ti a ki yio mọ̀.

27. Ohun ti mo ba wi fun nyin li òkunkun, on ni ki ẹnyin ki o sọ ni imọlẹ; ati eyi ti ẹnyin gbọ́ si etí ni ki ẹ kede rẹ̀ lori ile.

28. Ẹ má fòiya awọn ẹniti ipa ara, ṣugbọn ti nwọn ko le pa ọkàn: ṣugbọn ẹ kuku fòiya ẹniti o le pa ara ati ọkàn run li ọrun apadi.

29. Ologoṣẹ meji ki a ntà ni owo idẹ kekere kan? bẹ̃ni ko si ọkan ninu wọn ti yio ṣubu silẹ lẹhin Baba nyin.

30. Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan.

31. Nitorina ẹ má fòiya; ẹnyin ni iye lori jù ọ̀pọ ologoṣẹ lọ.

32. Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, on li emi o jẹwọ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.

33. Ṣugbọn bi ẹnikan ba si sẹ mi niwaju enia, on na li emi o sẹ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.

34. Ẹ máṣe rò pe emi wá rán alafia si aiye, emi ko wá rán alafia bikoṣe idà.

35. Mo wá lati yà ọmọkunrin ni ipa si baba rẹ̀, ati ọmọbinrin ni ipa si iya rẹ̀, ati ayamọ si iyakọ rẹ̀.