Yorùbá Bibeli

Mal 1:4-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nitori Edomu wipe, A run wa tan, ṣugbọn awa o padà, a si kọ ibùgbe ahoro wọnni; bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Nwọn o kọ, ṣugbọn emi o wo lulẹ; Nwọn o si pe wọn ni, Agbègbe ìwa buburu, ati awọn enia ti Oluwa ni ikọnnu si titi lai.

5. Oju nyin o si ri, ẹnyin o si wipe, A o gbe Oluwa ga lati oke agbègbe Israeli wá.

6. Ọmọ a ma bọla fun baba, ati ọmọ-ọdọ fun oluwa rẹ̀: njẹ bi emi ba ṣe baba, ọla mi ha da? bi emi ba si ṣe oluwa, ẹ̀ru mi ha da? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi fun nyin: Ẹnyin alufa, ti ngàn orukọ mi. Ẹnyin si wipe, Ninu kini awa fi kẹ́gàn orukọ rẹ?

7. Ẹnyin fi akarà aimọ́ rubọ lori pẹpẹ mi; ẹnyin si wipe, Ninu kini awa ti sọ ọ di aimọ́? Ninu eyi ti ẹnyin wipe, Tabili Oluwa di ohun ẹgàn.

8. Bi ẹnyin ba si fi eyi ti oju rẹ̀ fọ́ rubọ, ibi kọ́ eyini? bi ẹnyin ba si fi amúkun ati olokunrùn rubọ, ibi kọ́ eyini? mu u tọ bãlẹ rẹ lọ nisisiyi; inu rẹ̀ yio ha dùn si ọ, tabi yio ha kà ọ si? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.