Yorùbá Bibeli

Mak 5:33-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Ṣugbọn obinrin na ni ibẹ̀ru ati iwarìri, bi o ti mọ̀ ohun ti a ṣe lara on, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ gbogbo otitọ fun u.

34. O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia, ki iwọ ki o si sàn ninu arun rẹ.

35. Bi o si ti nsọ̀rọ li ẹnu, awọn kan ti ile olori sinagogu wá ti o wipe, Ọmọbinrin rẹ kú: ẽṣe ti iwọ si fi nyọ olukọni lẹnu?

36. Lojukanna bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ na ti a sọ, o si wi fun olori sinagogu na pe, Má bẹ̀ru, sá gbagbọ́ nikan.

37. Kò si jẹ ki ẹnikẹni tọ̀ on lẹhin, bikoṣe Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu arakunrin Jakọbu.

38. O si wá si ile olori sinagogu, o si ri ariwo, ati awọn ti nsọkun ti nwọn si npohunrere ẹkún gidigidi.

39. Nigbati o si wọle, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi npariwo, ti ẹ si nsọkun? ọmọ na ko kú, ṣugbọn sisùn li o sùn.

40. Nwọn si fi rẹrin ẹlẹya. Ṣugbọn nigbati o si tì gbogbo wọn jade, o mu baba ati iya ọmọ na, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, o si wọ̀ ibiti ọmọ na gbé dubulẹ si.

41. O si mu ọmọ na li ọwọ́, o wi fun u pe, Talita kumi; itumọ eyi ti ijẹ Ọmọbinrin, mo wi fun ọ, Dide.

42. Lọgan ọmọbinrin na si dide, o si nrìn; nitori ọmọ ọdún mejila ni. Ẹ̀ru si ba wọn, ẹnu si yà wọn gidigidi.

43. O si paṣe fun wọn gidigidi pe, ki ẹnikẹni ki o máṣe mọ̀ eyi; o si wipe, ki nwọn ki o fun u li onjẹ.