Yorùbá Bibeli

Mak 2:18-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Awọn ọmọ-ẹhin Johanu, ati awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi a ma gbàwẹ: nwọn si wá, nwọn si bi i pe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin Johanu, ati awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi fi ngbàwẹ, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko gbàwẹ?

19. Jesu si wi fun wọn pe, Ẹnyin le mu ki awọn ọmọ ile iyawo gbàwe, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? niwọn igbati nwọn ni ọkọ iyawo lọdọ wọn, nwọn kò le gbàwẹ.

20. Ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn o gbàwẹ ni ijọ wọnni.

21. Ko si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun mọ ogbologbo ẹ̀wu; bi bẹ̃ko eyi titun ti a fi lẹ ẹ a fà ogbologbo ya, aṣọ a si ma ya siwaju.

22. Ko si ẹniti ifi ọti-waini titun sinu ogbologbo ìgo; bi bẹ̃kọ ọti-waini titun a bẹ́ ìgo na, ọti-waini a si danu, ìgo na a si fàya; ṣugbọn ọti-waini titun ni ã fi sinu ìgo titun.

23. O si ṣe, bi Jesu ti nkọja lọ lãrin oko ọkà li ọjọ isimi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà bi nwọn ti nlọ.