Yorùbá Bibeli

Mak 14:23-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. O si gbe ago, nigbati o si sure tan, o fifun wọn: gbogbo nwọn si mu ninu rẹ̀.

24. O si wi fun wọn pe, Eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia.

25. Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi yio fi di ọjọ na, nigbati emi o mu u ni titun ni ijọba Ọlọrun.

26. Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi.

27. Jesu si wi fun wọn pe, Gbogbo nyin ni yio kọsẹ̀ lara mi li oru oni: nitoriti a ti kọwe rẹ̀ pe, Emi o lù oluṣọ agutan, a o si tú agbo agutan ká kiri.

28. Ṣugbọn lẹhin igba ti mo ba jinde, emi o ṣaju nyin lọ si Galili.

29. Ṣugbọn Peteru wi fun u pe, Bi gbogbo enia tilẹ kọsẹ̀, ṣugbọn emi kọ́.

30. Jesu si wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ pe, loni yi, ani li alẹ yi, ki akukọ ki o to kọ nigba meji, iwọ o sẹ́ mi nigba mẹta.

31. Ṣugbọn o tẹnumọ ọ gidigidi wipe, Bi o tilẹ di ati ba ọ kú, emi ko jẹ sẹ́ ọ bi o ti wù ki o ri. Gẹgẹ bẹ̃ni gbogbo wọn wi pẹlu.

32. Nwọn si wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane: o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi, nigbati mo ba lọ igbadura.

33. O si mu Peteru ati Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀, ẹnu si bẹrẹ si yà a gidigidi, o si bẹré si rẹ̀wẹsi.

34. O si wi fun wọn pẹ, Ọkàn mi nkãnu gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihin, ki ẹ si mã ṣọna.

35. O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ, o si gbadura pe, bi o ba le ṣe, ki wakati na le kọja kuro lori rẹ̀.

36. O si wipe, Abba, Baba, ṣiṣe li ohun gbogbo fun ọ; mú ago yi kuro lori mi: ṣugbọn kì iṣe eyiti emi fẹ, bikoṣe eyiti iwọ fẹ,

37. O si wá, o ba wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Simoni, iwọ nsùn? iwọ kò le ṣọna ni wakati kan?

38. Ẹ mã ṣọna, kì ẹ si mã gbadura, ki ẹ má ba bọ́ sinu idẹwò. Lõtọ li ẹmí nfẹ, ṣugbọn o ṣe ailera fun ara.

39. O si tún pada lọ, o si gbadura, o nsọ ọ̀rọ kanna.

40. Nigbati o si pada wá, o tún bá wọn, nwọn nsùn, nitoriti oju wọn kún fun orun, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀ èsi ti nwọn iba fifun u.

41. O si wá li ẹrinkẹta, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã sùn wayi, ki ẹ si mã simi: o to bẹ̃, wakati na de; wo o, a fi Ọmọ-enia le awọn ẹlẹṣẹ lọwọ.