Yorùbá Bibeli

Mak 11:26-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba dariji, Baba nyin ti mbẹ li ọrun kì yio si dari ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin.

27. Nwọn si tún wá si Jerusalemu: bi o si ti nrìn kiri ni tẹmpili, awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn agbàgba, tọ̀ ọ wá,

28. Nwọn si wi fun u pe, Aṣẹ wo li o fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi lati mã ṣe nkan wọnyi?

29. Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi ó bi nyin lẽre ọ̀rọ kan, ki ẹ si da mi lohùn, emi o si sọ fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.

30. Baptismu Johanu lati ọrun wá ni, tabi lati ọdọ enia? ẹ da mi lohùn.

31. Nwọn si ba ara wọn gbèro, wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni: on o wipe, Ẽha ti ṣe ti ẹnyin ko fi gbà a gbọ́?

32. Ṣugbọn bi awa ba wipe, Lati ọdọ enia; nwọn bẹ̀ru awọn enia: nitori gbogbo enia kà Johanu si woli nitõtọ.

33. Nwọn si dahùn wi fun Jesu pe, Awa kó mọ̀. Jesu si dahùn wi fun wọn pe, Emi kì yio si wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.