Yorùbá Bibeli

Mak 1:35-45 Yorùbá Bibeli (YCE)

35. O si dide li owurọ̀ ki ilẹ to mọ́, o si jade lọ si ibi iju kan, nibẹ li o si ngbadura.

36. Simoni ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si nwá a.

37. Nigbati nwọn si ri i, nwọn wi fun u pe, Gbogbo enia nwá ọ.

38. O si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ilu miran, ki emi ki o le wasu nibẹ̀ pẹlu: nitori eyi li emi sá ṣe wá.

39. O si nwãsu ninu sinagogu wọn lọ ni gbogbo Galili, o si nlé awọn ẹmi èṣu jade.

40. Ọkunrin kan ti o dẹtẹ si tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ niwaju rẹ̀, o si mbẹ̀ ẹ, o si wi fun u pe, Bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́.

41. Jesu ṣãnu rẹ̀, o nà ọwọ́ rẹ̀, o fi bà a, o si wi fun u pe, Mo fẹ, iwọ di mimọ́.

42. Bi o si ti sọ̀rọ, lojukanna ẹ̀tẹ na fi i silẹ; o si di mimọ́.

43. O si kìlọ fun u gidigidi, lojukanna o si rán a lọ;

44. O si wi fun u pe, Wo o, máṣe sọ ohunkohun fun ẹnikẹni: ṣugbọn lọ, fi ara rẹ hàn fun alufa, ki o si fi ẹ̀bun iwẹnumọ́ rẹ ti Mose ti palaṣẹ, ni ẹrí fun wọn.

45. Ṣugbọn o jade, o si bẹrẹ si ikokiki, ati si itàn ọ̀ran na kalẹ, tobẹ̃ ti Jesu kò si le wọ̀ ilu ni gbangba mọ́, ṣugbọn o wà lẹhin odi nibi iju: nwọn si tọ̀ ọ wá lati ìha gbogbo wá.